HYMN 19

(FE 36)
C.M.S 15, H.C 20, 10s
"Ba wa duro, nitori o di oju ale" 
- Luku 24:29


1. WA ba mi gbe Ale fere le tan,

   Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe 

   Bi oluranlowo miran ba ye 

   lranwo alaini, wa ba mi gbe!


2. Ojo aiye mi nsare lo s’opin 

   Ayo aiye nkun, ogo re nwo mi, 

   Ayida at’ibaje ni mo nri

  Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe.


3. Ma wa l'eru b‘Oba awon Oba, 

   Sugbon ki O ma bo b‘oninu re 

   Ki o si ma kanu fun egbe mi 

   Wa, ore elese, wa ba mi gbe!


4. Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo 

   Kil'o le segun Esu b‘ore Re? 

   Tal‘o le se amona mi bi Re? 

   N'nu 'banuje at' ayo ba mi gbe!


5. Pelu 'bukun Re, eru ko ba mi
 
   lbi ko wuwo, ekun ko koro

   Oro iku da? ‘segun isa da

   Ngo segun sibe, b'lwo ba mi gbe.


6. Wa ba mi gbe ni wakati iku 

   Se 'mole mi, si toka si orun

   B'aiye ti nkoja, k'ile orun mo

   Ni yiye, ni kiku, wa ba wa gbe. Amin

English »

Update Hymn