HYMN 198

(FE 217) Tune: 7.6.7.6.7.6.7.6.
“Imole na si nmole" - John 1:51.  A YIN O, Baba orun 

T'O ran ‘mole w‘aiye 

Lati wa tan ‘mole Re; 

Si okunkun aiye 

Angeli nkorin wipe 

Ogo f’Oba t'a bi

Ni ilu nla Dafidi

Ti nse Krist' Oluwa.


2.  K'eda aiye ko gberin 

K'eda orun gberin 

S’Omo Mimo Dafidi 

Omo ti Ileri

Yin Omo Alade nla 

Ade alafia 

K’ibukun ojo oni 

Ko kari gbogbo wa.


3.  O wa ninu irele

Lati ko wa leko

K’a tele ‘pa ese Re 

Ka le gba ‘leri Re 

Gbo, eda orun nkorin 

Iyin f’OIugbala 

Alafia l'aiye yi

Baba ba wa laja.


4.  O to igbekun sile

O so wa di Tire

K'a ma d'eru ese mo 

K‘a d‘eni igbala 

lyin, Ola, Agbara, 

Ni fun baba loke 

Ogo ni fun Omo Re 

Ni fun Emi Mimo.


5.  Kembu on Serafu

So fun araiye pe

Ijoba ku si dede

Ijoba Olorun

‘Gba Jesu y’o tun w'aiye 

Bi Onidajo Nla

K’a le fi ayo pade Re 

Baba, gbo ebe wa.  Amin

English »

Update Hymn