HYMN 2

t. H.C.2 L.M(FE19)


1. Mo ji, Mo ji, Ogun orun

   K'emi l'agbara bi ti nyin

   K'emi ba le lo ojo mi 

   Fun iyin Olugbala mi.


2. Ogo fun Eru‘ o so mi 

   To tu mi lara loju Orun

   Oluwa ijo mo ba ku

   Ji mi s‘iye ainipekun.


3. Oluwa mo tun eje je 

   Tu ese ka b'iri oro

   So akoronu mi oni

   Si f‘Emi Re kun inu mi.


4. Oro at'ise mi oni

   Ki nwon le re bi eko Re 

   K'emi si f‘ipa mi gbogbo 

   Sise rere fun Ogo Re. Amin

English »

Update Hymn