HYMN 208

C.M.S. 79 t.H.C. 14 L.M. (FE 228) 
"Mo mu ihin aho nlanla fun yin wa."
 - Luku 2:101. OJO ayo nlanla na de, 

   Eyit’ araiye ti nreti; 

   Nigbati’ Olugbala W’ aiye, 

   Nigbat'a bi ninu ara.


2. Olus’agutan ni papa,

   Bi nwon ti so agutan won, 

   Ni ihin ayo na ko ba, 

   lhin bibi Olugbala.


3. Angel iranse Oluwa,

   L‘ a ran si won, alabukun, 

   Pelu ogo t’ o ntan julo, 

   Lati so ihin ayo yi.


4. Gdigidi l' eru ba won, 

   Fun ajeji iran nla yi; 

   “Ma beru" l’ oro iyanju, 

   T' o t'enu Angeli wa.


5. A bi Olugbala loni, 

   Kristi Oluwa aiye ni;

   N‘ ilu nla Dafidi I’ O wa, 

   N' ibuje eran l‘a te si.


6. “Ogo fun Olorun' l’orin, 

   Ti enia y'o ko s’orun; 

   Fun ife Re laini opin,

   T' o mu alafia w‘ aiye. Amin

English »

Update Hymn