HYMN 218

8s. 8s. 6s. (FE 237)
"Ogo Oluwa yio wa Iailai”
Ohun Orin: “Lehin aiye buburu”1. ODUN titun de awa nyo, 

   Tiwa to be, o ju be lo,

   Aw' Egbe Serafu,

   Ko ni gbagbe l’odun to lo, 

   K’ Olorun se ‘yi l’odun 're, 

   E ku ewu odun.


2. Enyin Om'Egbe Kerubu, 

   K’ e sotiti titi d’opin,

   K‘ emura s’ adura,

   K’ ema woju enikeni,

   E gboran si agba l’ enu, 

   E ye ‘ra odun wo.


3. Enyin Egbe Aladura,

   K‘ e ranti iran ti e nri, 

   S'ipa iwa rere,

   K’ e mura lati d‘ ohun po, 

   E se ara nyin ni okan,

   E ye ‘ra odun wo.


4. Awon ti ko gba iran gbo, 

   Nwon dabi ako keferi; 

   Nwon ko mo ‘kan s’okan,

   Bere lowo Jenny Winful,

   Ohun t' ori k’ o to bimo,

   E ye ‘ra odun wo.


5. K’ a fi keta gbogbo sile, 

   k’ a fe om’ enikeji wa, 

   L’ odun t’ a bo si yi,

   K’ a m soro eni lehin,

   K’ ija gbogbo kuro l’ona, 

   E ye ‘ra odun wo.


6. Ninu odun t’ a bo si yi,

   Agan a f’ owo s’ osun,

   Olomo a tun bi,

   Enit’ o je ‘gbese y’osan,

   Aje, oso ko ni ri wa,

   E ye ‘ra odun wo.


7. E wo bi ilu wa ti ri, 

   Ajakal’ arun tun gb'ode, 

   K’Olorun mu kuro,
  
   Nipa awe at‘adura, 

   K’okan gbogbo wa nirepo, 

   E ye ‘ra odun wo.


8. A ko ri ra, a ko ri ta,

   Ko tun s’ awon alanu mo, 

   Owo ko si l’ode,

   Ibawi Olorun l’eyi,

   K’a ronu k’ a p’iwa wa da, 

   Eye ra odun wo.


9. Nigbat‘ o ba d’ojo ‘kehin

   Ti omo ko ni mo baba, 

   Oluwa, ranti mi,

   K’a le gbo ohun ‘kele ni, 

   Wipe, ma bo, omo rere,

   K’ a gb’ ade nikehin. Amin

English »

Update Hymn