HYMN 221

H.C 513.8.9 8.8 (FE 240) 
"Ki enyin ki o si ma yo niwaju
Oluwa Olorun nyin" - Lefit. 23:40 
(Tune: A nsoro ile‘bukun ni)1. A ki gbogbo nyin ku odun, 

E ku ajoy’odun titun 

E jek’a sope f'Oluwa 

T'o da Emi wa si d'oni.


2. Opo omode at’agba

T’o ti ngbo ‘mura ajodun yi, 

Opolopo ti koja lo

Won ti file bora b'aso.


3. Egbe agba alatunse

   E ku atunse egbe na 

   Baba orun yio pelu nyin 

   Yio fi nyin s‘agba kale.


4. A ki Bale p'e ku odun 

   Ati gbogb’ awon ljoye 

   E ku itoju ilu yi

   Oluwa yio ran yin lowo.


5. Mase foiya onigbagbo 

   Jesu yio pese l‘odun yi 

   Eni ko bi, iyen a bi 

   Eni bi tire a tunla.


6. B'ina ku a feru b'oju 

   B'ogede ku a f‘omo ropo 

   O daju pe b'o tile pe 

   Omo wa ni o ropo wa.


7. Gbogbo alejo, a ki nyin 

   At’ awon olufe owon

   Jesu yio toju ile nyin

   Yio si bukun gbogbo nyin.


8. A ki nyin pe E ku odun

   Odun titun t’a nse loni 

   K‘Olorun da emi wa si

   Ki gbogbo wa se t‘ amodun. Amin

English »

Update Hymn