HYMN 227

P.B C.M.S 101 C.M (FE 247)
‘Olorun si wipe ki imole ki o wa 
l’ofurufu fun ami, fun akako, fun ojo, 
ati fun odun" - Gen. 1:141. OLORUN wa je k'iyin Re 

   Gb'ohun gbogbo wa kan 

   Owo Re yi ojo wa po 

   Odun miran si de.


2. Ebo wa ngoke sodo Re 

   Baba, Olore wa

   Fun anu ododun ti nsan 

   Lati odo Rewa.


3. N'nu gbogbo ayida aiye 

   K’anu Re wa sibe 

   B’ore Re si wa si ti po 

   Beni k’iyin wa po.


4. N'nu gbogbo ayida aiye 

   A nri aniyan Re

   Jowo je k'anu Re ‘kanna 

   Bukun odun titun.


5. B'ayo ba si wa, k’ayo na 

   Fa wa si odo Re

   B’iya ni awa o korin 

   B’ibukun Re pelu. Amin

English »

Update Hymn