HYMN 232

PB 62 CMS 98 (FE 252) 
“Nje Oluwa ni yi ma se Olorun mi”
- Gen. 28:211. OLORUN Betel, eniti

   O mbo awon Tire 

   Enit’o mu baba wa la 

   Ojo aiye won ja.


2. A mu eje, at’ebe wa 

   Wa iwaju ‘te Re 

   Olorun awon Baba wa 

   Ma je Olorun wa.


3. Ninu idamu aiye yi 

   Ma toju ipa wa

   Fun wa ni onje ojo wa 

   At’aso t'o ye wa.


4. Na ojiji ‘ye Re bo wa 

   Tit’ajo wa o pin

   Ati ni ‘bugbe Baba wa 

   Okan wa o simi.


5. Iru ibukun bi eyi 

   L’a mbere lowo Re

   Iwo o je Olorun wa, 

   At’ipin wa lailai. Amin

English »

Update Hymn