HYMN 233

C.M.S 104 S.M (FE 253) 
"Ese won l’ori oke ti dara to” - Isa. 52:71. ESE won ti da to 

   Ti nduro ni Sion

   Awon t‘o mu ‘hin gbala wa 

   Awon t‘o f’ayo han.


2. Ohun won ti wo to 

   Ihin na ti dun to

   Sion, w'Olorun Oba re 

   B’o ti segun nihin.


3. Eti wa ti yo to

   Lati gboro ayo

   Woli, Oba, ti duro de 

   Nwon wa, nwon ko siri.


4. Oju wa ti yo to

   To ri ’mole orun

   Oba, Woli, nwon wa titi 

   Nwon si ku, nwon ko ri.


5. Oluwa, f’ipa han

   Lori gbogbo aiye

   Ki gbogbo orile ede 

   W‘Oba Olorun won. Amin

English »

Update Hymn