HYMN 24

C.M.S 492, t.H.C 368, 6s 5s (FE41)
“Fi eti si mi Oluso aguntan Israeli”
 - Ps. 80:1


1. OLUS’ AGUTAN mi,

   Ma bo mi titi, 

   Olus’agutan mi,

   Ma to ese mi.


2. Di mi mu, si to mi, 

   Ni ona hiha 

   B’O ba wa lodo mi, 

   Emi ko sina.


3. Sin mi s’ona orun 

   Ni ojojumo

   Ma busi ‘gbagbo mi 

   Si mu mi fe O.


4. K'ayo at'alafia 

   Ti odo Re wa 

   K'iye ainipekun 

   Le je ayo mi.


5. Ma pese okan mi,

   Ni ojojumo

   Si je k‘Angeli Re, 

   Sin mi lo ile. Amin

English »

Update Hymn