HYMN 252

C.M.S 159, t.H.C 156 L.M (FE 272)
“OIuwa, kiyesi aroye mi" - Psalmu 5:1 1. OLUWA, gbo aroye mi

   Gbo adura ikoko mi 

   Lodo Re nikan Oba mi 

   L’emi O ma wa iranwo.


2. L’oro Iwo o gbohun mi 

   L’afemojumo ojo na 

   Ni odo Re l’emi o wo 

   Si O l’emi o gbadura.


3. Sugbon nigb’ore-ofe Re 

   Ba mu mi de agbala Re 

   Odo Re I'em’o teju mo 

   Nibe, ngo sin O ni rele.


4. Je k’awon t’o gbekele O, 

   L’ohun rara wi ayo won 

   Jek’ awon t’lwo pamo yo 

   Awon t’o fe oruko Re.


5. Si Olododo l’Oluwa

   O na owo ibukun Re

   Oju rere Re l’enia Re

   Yio si fi se asa won. Amin

English »

Update Hymn