HYMN 255

C.M.S 163 .t.H.C 152 CM (FE 275)
“Olorun, sanu fun mi elese" - Luku 18:13
1. OLU WA, b’agbowode ni 

   Mo gb’okan mi le O 

   Oluwa, f' ore-ofe wi

   K‘o se anu fun mi.


2. Mo lu aiduro aiya mi 

   Ekun at’irora

   K‘o gb'okan mi’nu irora 

   K’o se anu fun mi.


3. N'itiju, mo jew’ ese mi 

   Jo fun mi ni ireti

   Mo be, ‘tori eje Jesu 

   K’o se anu fun mi.


4. Olori elese ni mi 

   Ese mi p‘apoju 

   Nitori iku Jesu wa 

   K’O se anu fun mi.


5. Mo duro ti agbelebu 

   Nko sa f’ojiji re

   Ti Olorun to po l’anu

   O ti sanu fun mi. Amin

English »

Update Hymn