HYMN 257

C.M.S 173 H.C 160 D 6s 5s (FE 277)
"Mo ti gbadura fun o, ki igbagbo 
re mase ye" - Luku 22:321. JESU, nigba ‘danwo 

   Gbadura fun mi 

   K‘emi ma ba se O 

   Ki nsi sako lo

   Gba mba siyemeji 

   K'O bojuwo mi 

   K’eru tab‘isaju 

   Ma mu mi subu.


2. B’aiye ba si nfa mi 

   Pelu adun re 

   T’Ohun ‘sura aiye 

   Fe han mi l’emo 

   Jo mu Getsemane 

   Wa s’iranti mi 

   Tabi irora Re, 

   loke Kalfari.


3. B‘O ba pon mi loju 

   Ninu ife Re 

   Da ibukun Re Ie 

   Ori ebo na

   Ki nf'ara mi fun O 

   Lori pepe Re 

   B’ara ko ago na 

   Igbagbo y'o mu.


4. ‘Gba mo ba nre ‘boji 

   Sinu ekuru

   T'ogo orun si nko 

   Leti bebe na

   Ngo gbekel’oto Re 

   N'ijakadi ‘ku 

   Oluwa, gb'emi mi 

   S‘iye ailopin. Amin

English »

Update Hymn