HYMN 258

C.M.S 173 H.C 163. D 7s 6s. (FE 278)
"Eni itewogba ninu Ayanfe" - Efe. 1:6s
1. MO kese mi le, Jesu 

   Od'agutan Mimo

   O ru gbogbo eru mi 

   O so mi d' ominira 

   Mo ru ebi mi to wa 

   K’o we eri mi nu

   K'eje Re iyebiye 

   Le so mi di funfun.


2. Mo k‘aini mi le Jesu 

   Tire l'ohun gbogbo 

   Ow‘arun mi gbogbo san 

   O r'emi mi pada

   Mo ko ibanuje mi 

   Eru at'aniyan 

   Le Jesu, O si gba mi 

   O gba irora mi.


3. Mo gb'okan mi le Jesu 

   Okan ara mi yi 

   Ow’otun Re gba mi mu 

   Mo simi laya Re

   Mo fe oruko Jesu 

   Emmanuel, Kristi. 

   Bi orun didun yika 

   Ni oruko Re je.


4. Mo fe ki nri bi Jesu 

   Tokan Re kun fun ‘fe 

   Mo fe ki nri bi Jesu 

   Omo Mimo Baba

   Mo fe ki mba Jesu gbe 

   Larin egbe mimo

   Ki nkorin iyin titi

   Orin t‘Angeli nko. Amin

English »

Update Hymn