HYMN 267

C.M (FE 287)
"Oju Oluwa mbe nibi gbogbo"
 - Owe 15:31. ISE gbogbo ti awa nse 

   Ni Olorun ti ri

   Ero gbogbo t'o wa ninu 

   Ni Olorun si mo.


2. A ko le f‘ese wa pamo 

   Gbogbo won l'O ti mo 

   A npuro, a ntan ‘ra wa je 

   B’a ro pe ko mo won.


3. Ohun gbogbo han ni gbangba 

   Ni oju Olorun

   Okunkun ati imole

   Si ri bakanna fun.


4. Olorun, je k'a ranti pe 

   Oju re si ri wa

   Si jeki awa k’o beru 

   Lati dese si O. Amin

English »

Update Hymn