HYMN 28

(FE45)
Ohun Orin - E je k'a f'inu didun


1. OLORUN ojo ‘simi 

   Sokale l’agbara Re 

   Pase ‘bukun t’oke wa 

   Je ka ri O larin wa.


2. Je ka O ka ri O

   Ni Olorun Kerubu 

   Ko ran ife rere Re 

   Sarin Egbe Serafu.


3. Mu ki gbogbo agbaiye 

   Teti soro mimo Re, 

   M'alagidi teriba 

   S’okan t'o ku d’alaye.


4. Eni nwa O ko ri O,

   Eni nsubu gbe dide; 

   W‘alaisan, at‘afoju,

   Ki gbogbo wa jo yin O.


5. Bukun oro mimo Re, 

   To ran wa lakoko yi, 

   Je k'aiye fi se ‘wa hu 

   L'agbara Metalokan.


6. Ogo ni fun Baba wa,

   Ogo ni fun Omo Re,

   Ogo ni f'Emi Mimo
 
   Ogo fun Metalokan. Amin

English »

Update Hymn