HYMN 283

C.M.S 147 H.C 154 C.M (FE 303) 
“Oluwa, ranti mi" - Luku 23:421. lWO Iow’enit' ire nsan 

   Mo gb’okan mi si O

   Ni ‘ibanuje at’ise mi, 

   Oluwa, ranti mi.


2. ‘Gba mo nkerora l'okan mi 

   T‘ese wo mi l’orun

   Dari gbogbo ese ji mi

   Ni ife, ranti mi.


3. ‘Gba 'danwo kikan yi mi ka 

   Ti ibi le mi ba

   Oluwa, fun mi l’agbara

   Fun rere, ranti mi.


4. Bi ‘tiju at'egan ba de

   ‘Tiro oruko re

   Ngo yo s’egan, ngo gba t'iju, 

   B‘iwo ba ranti mi.


5. Oluwa, gba iku de

   Em’ o sa ku dandan; 

   K‘eyi j’adura gbehin mi, 

   Oluwa, ranti mi. Amin

English »

Update Hymn