HYMN 284

C.M.S 184 k. 151
t.h.e 147 c.m. (FE 305)
“Kristi at'aaroni” - Heb. 7:111. JESU, l’ara re l’awa nwo 

   Egbegberun ogo

   Ju t'okuta iyebiye 

   T'agbada Aaroni.


2. Nwon ko le sai ko rubo na, 

   Fun ese ara won

   lwa re pe, ko l'abawon 

   Mimo si l’eda re.


3. Jesu oba ogo gunwa 

   L‘oke Sion t’orun

   Bi odo-agutan t'a pa 

   Bi alufa nla wa.


4. Alagbawi lodo Baba

   Ti y’o wa titi lai

   Gb'ejo re fun ‘wo okan mi 

   Gb'ore-ofe baba. Amin

English »

Update Hymn