HYMN 288

C.M.S 196 H.C 460 C.M (FE 309)
"Hosannah fun Omo Dafidi" - Matt 21:91. HOSANNA s'Omo Dafidi 

   Hosanna, e korin

   ‘Olubukun l’Eniti mbo 

   L'oruko Oluwa.


2. Hosanna s’Omo Dafidi

   L’Egbe Angeli nke

   Gbogbo eda jumo gberin 

   Hosanna s'Oba wa.


3. Hosanna! awon Heberu 

   Ja imo ope sona 

   Hosanna a mu ebun wa 

   Fi tun ona Re se.


4. T'agba t’ewe nke Hosanna! 

   K‘ijiya Re to de;

   Loni, a si nko Hosanna! 

   B’O ti njoba l’oke.


5. 'B’O ti gba ‘yin won nigbana 

   Jo gba ebe wa yi

   Lorun ka le b’angel 'korin 

   Hosanna s'Oba wa. Amin

English »

Update Hymn