HYMN 289

H.C 144. 7s (FE 310)
“Lati inu ibu wa Ii emi kepe O,
Oluwa" - Ps. 130:11. ‘WO t’o ku ni Kalfari 

   Wo t’o mbebe f‘elese 

   Ran mi lowo, nigb’aini 

   Jesu, gbo ‘gbe mi.


2. Ninu ibanuje mi, 

   At‘okan aigbagbo mi 

   Em'olori elese

   Gb’oju mi si O.


3. Ota lode, eru n’nu 

   Ko s’ire kan lowo mi 

   Iwo t’o ngb’elese la 

   Mo sa to O wa.


4. Awon miran dese pe 

   Nwon si ri igbala 

   Nwon gbo ohun anu Re 

   Mu mi gbo pelu.


5. Mo k’aniyan mi le O 

   Mo si ngbadura si O, 

   Jesu, yo mi n'nu egbe 

   Gba mi, ki nma ku.


6. ‘Gbati wahala ba de 

   Nigb’ agbara idanwo 

   Ati lojo ikehin

   Jesu, sunmo mi. Amin

English »

Update Hymn