HYMN 295

FRIDAY RERE

H.C 190 L.M (FE 316)
“Emi nsokun nitori nkan wonyi oju mi?
Oju mi san omi sile" - Ekun 1:161. ARA, ewa ba mi sofo 

   E wa sodo Olugbala

   Wa, e je k‘a jumo sofo 

   A kan Jesu m'agbelebu.


2. Ko ha s'omije loju wa 

   Bi awon Ju ti nfi sefe?

   A! e wo, b’O ti teriba

   A kan Jesu m‘agbelebu.


3. Emeje l' Osoro ife 

   Idake wakati meta 

   L’o fi ntoro anu f’enia 

   A kan Jesu m'agbelebu.


4. Bu s'ekun, okan lile mi! 

   Ese at‘igberaga re

   L’o da Oluwa re l'ebi

   A kan Jesu m’agbelebu.


5. Wa duro ti agbelebu 

   K'eje ti njade niha Re 

   Ba le ma san le o lori; 

   A kan Jesu m’agbelebu.


6. lbanuje at‘omije

   Bere a ki o fi du o 

   ‘Banuje l'o nf‘ife re han 

   A kan Jesu m’agbelebu.


7. lfe Baba, ese eda, 

   Nihin l’a ri agabra re 

   lfe l‘o si di Asegun

   A kan Olufe wa mo ‘gi. Amin

English »

Update Hymn