HYMN 296

H.C 195 8s. 7s (FE 317)
“O pari" - John 19:301. E gb‘ohun ife at‘anu 

   Ti ndun l‘oke Kalfari! 

   Wo! o san awon apta! 

   O mi le, o m' orun su! 

   ‘O ti pari "O ti pari“ 

   Gbo b’Olugbala ti ke.


2. ‘0 ti pari! b'o ti dun to 

   Ohun t’oro wonyi wi 

   lbukun orun l‘ainiye 

   Ti odo Kristi san si wa 

   ‘O ti pari. “O ti pari"

   E ranti oro wonyi.


3. Ise igbala wa pari,

   Jesu ti mu ofin se

   O pari, nkan t'Olorun wi 

   Awa ki o ka ‘ku si

  ‘O ti pari, ‘O ti pari, 

  Elese ipe l'eyi.


4. E tun harpu nyin se, Seraf 

   Larti korin ogo Re 

   Ar‘aiye at'ara orun

   Yin ‘ruko Emmanuel

   ‘O ti pari, ‘O ti pari 

   Ogo fun Od’aguntan. Amin

English »

Update Hymn