HYMN 298

H.C 191 8s. 7s (FE 319) 8787
"Koju si mi ki a si gba nyin la”
 - Isa 45:221. WAKATI didun ni fun mi 

   Ni wiwo agbelebu

   Nibe Jesu fun mi n’iye

   ‘Lera at'alafia.


2. Nihin l'emi o gbe joko

   Lati wo isun eje

   Eyiti y‘o we okan mi

   K'Olorun ba le gba mi.


3. Niwaju agbelebu Re

   L’emi o ba buruburu

   ‘Gbati emi bari ‘yonu nla 

   T’o farahan loju Re.


4. lfe ati omije mi

   Ni ngo fi we ese re

   Tori mo mo pe iku Re 

   Y’o mu iye wa fun mi.


5. Oluwa, jo gba ebe mi,

   Se okan mi ni Tire

   Tit’ emi o fi ri ‘gbala 

   At'oju Re n'nu ogo. Amin

English »

Update Hymn