HYMN 3

C.M.S.2t, S. 634, CM (FE 20)
"Emi dubule, mo si su, mo si ji Nitori 
Oluwa ti mi Iehin" - Ps. 3:5


1.  Ninu gbogbo ewu oru, 

Oluwa l‘o so mi

Awa si tun ri' mole yi 

A tun te ekun ba.


2.  Oluwa, pa wa mo l'oni, 

Fi apa Re so wa;

Kiki awon ti ‘Wo pamo 

L‘o nyo ninu ewu.


3.  K’oro wa, ati iwa wa 

Wipe, Tire l'awa, 

Tobe t'imole otito 

Le tan l‘oju aiye.


4.  Ma je k’a pada lodo Re, 

Olugbala owon

Titi a o f'oju wa ri,

Oju Re li opin.  Amin

English »

Update Hymn