HYMN 303

L.M.1. OLUGBALA mi ha gbogbe! 
  
   Oba ogo ha ku! 

   On ha je f'ara Re rubo 

   F'eni ile b’emi?


2. lha se ese ti mo da 

   L'o gbe ko s‘ori igi? 

   Anu at‘ore yi ma po 

   lfe yi rekoja!


3. O ye k‘orun f'oju pamo 

   K‘o b‘ogo re mole 

   ‘Gbati Kristi Eleda ku 

   Fun ese eda Re.


4. Be l‘o ye k’oju ba ti mi 

   ‘Gba mo r’agbelebu

   O ye k’okan mi kun f'ope 

   Oju mi f’omije.


5. Sugbon omije ko le san 

   Gbese ‘fe ti mo je

   Mo f'ara mi f’Oluwa mi 

   Eyi ni mo le se. Amin

English »

Update Hymn