HYMN 310

8s. 6s. (FE 331)
"Kiyesi i, Olorun li Oluranlowo mi"
- Ps. 54:4
Tune: 8s 6 Bi mo ti ri laisawawi1. JESU Oluwa awa de, 

   Loni Ojo Ajinde wa, 

   Lati gb’okan s’oke, 

   Si Oruko re Mimo ni.


2. Ba wa pe Olorun Baba, 

   Ba wa pe Olorun Omo,

   Ba wa pe Olorun Emi,

   Wa so gbogbo wa di mimo.


3. Lojo oni, awa dupe,

   Teru teru l’awa josin, 

   Gba wa lowo aiye osi yi, 

   Ma jek’ a s' esin laiye yi.


4. Hosana s’ Oba Olore, 

   A dupe fun Ajinde yi, 

   F‘ Enikan na to jinde, 

   A sope fun Metalokan.


5. Ogo ni fun Baba l’oke 

   Ogo ni fun Omo pelu, 

   Ogo ni fun Emi Mimo, 

   Ogo ni f‘ Olodumure. Amin

English »

Update Hymn