HYMN 315

H.C. 202 t. 449 6. 7s. (FE 338)
Tune: Apata Aiyeraiye.
“Je ki a se lala lati wo inu isimi na."
 - Heb. 4:111. ISIMI awon mimo,

   Ojo ohun ijinle,

   Apere isimi Re,

   Oluwa simi 'se Re,

   O ya 'jo na si mimo.


2. Loni oku Oluwa, 

   Nsimi ninu iboji; 
 
   A ti we l’ aso oku, 

   Lat' ori titi d'ese, 

   A si fi okuta se, 

   A si ti edidi di.


3. Oluwa, titi aiye,

   L' a o ma pa eyi mo, 

   A’ o t’ ilekun pinpin, 

   K' ariwo ma ba wole,

   A o fi suru duro, 

   Tit’ lwo o tun pada.


4. Gbogbo awon t’ o ti sun, 

   Nwon o wa ba O simi; 

   Nwon o bo lowo lala, 

   Nwon nreti ipe ‘kehin, 

   T' a o di eda titun,

   T' ayo wa ki y’o l' opin.


5. Jesu yo wa nin’ ese

   K’ a ba le ba won wole,

   Ewu ati ‘se y’ o tan,

   A o f' ayo goke Io,

   A o ri Olorun wa,

   A o si ma sin lailai. Amin

English »

Update Hymn