HYMN 318

C.M.S. 217 H.C 203 8.7.8.3 (FE 341)
“Yio te mi l'orun nigbati mo ba ji 
I'aworan Re" - Ps. 17:151. L‘OWURO ojo Ajinde 

   T‘ara t'okan yio pade 

   Ekun, kanu on irora 

   Y'o dopin.


2. Nihin nwon ko le sai pin ya, 

   Ki ara ba le simi

   K’o si fi idakeroro

   Sun fonfon.


3. Fun ‘gba die era are yi

   L’a gbe s‘ibi ‘simi re 

   Titi di imole oro

   Ajinde.


4. Okan t’o kanu nisiyi 

   T’o si ngbadura kikan 

   Y’o bu s'orin ayo l'ojo Ajinde.


5. Ara at’okan y’o dapo 

   Ipinya ko ni si mo

   Nwon o ji l’aworan Krist’ ni 

   ‘Telorun.


6. A! ewa na at'ayo na 

   Y’o ti po to Ajinde! 

   Y'o duro b‘orun at’aiye 

   Ba fo lo.


7. L'oro ojo Ajinde wa, 

   ‘Boji y’o m'oku re wa 

   Baba, iya, omo, ara 

   Y'o pade.


8. Si dapo ti o dun bayi

   Di Jesu, masai ka wa ye 

   N'nu ‘ku dajo, k‘a le ro 

   M'a Gbelebu. Amin

English »

Update Hymn