HYMN 332

(FE 335) C.M.S 233 t.S.634 C.M
“Eyara lo so fun awon omo ehin Re
pa O jinde" - Matt. 28:71. MO wi fun olukaluku 

   Pe, On ji, O si ye

   O si wa larin wa pelu 

   Nipa Emi iye.


2. E wi fun enikeji nyin 

   Ki nwon ji pelu wa 

   K’imole k’o wa kakiri 

   Ni gbogbo aiye wa.


3. Nisisiyi aiye yi ri

   Bi ile Baba wa

   lye titun ti On fun ni 

   O so d‘ile Baba.


4. Ona okun ti On ti rin 

   Mu ni lo si orun

   Enit’ o rin bi On ti rin 

   Y'o d'odo Re l'orun.


5. On ye, O si wa pelu wa 

   Ni gbogbo aiye yi

   Ati nigbati a f’ara wa, 

   F’erupe ni ‘reti. Amin

English »

Update Hymn