HYMN 337

P.B 167 11s (FE 360)
“Isimi kan ku fun awon enia Olorun"
- Heb. 4:91. KINI ‘Simi ayo ailopin ni

   T'awon Angeli at‘awon mimo ni? 

   Simi f‘alare, f’awon asegun

   Nibe I‘Olorun je ohun gbogbo.


2. Tal' Oba na? tani yi ‘te re ka 

   Irora itura Re na ti’ri?

   So funni, enyin ti njosin nibe 

   So funni, b' oro to t’ayo nyin so.


3. Jerusalem toto, ilu mimo 

   Alafia eyi t‘o je kik’ayo

   A r'ohun t’a nfe n'nu re k’a to wi 

   A si ri gba ju eyi t’a nfe lo.


4. L’agbala Oba wa, wahala tan 

   Laiberu l’ao ma korin Sion

   Oluwa, niwaju Re l'a o ma fi 

   Idahun ‘fe han f 'ebun ife Re.


5. Simi ko le tele ‘simi nibe 

   Enikan ni ‘simi ti nwoju Re

   Nibe orin jubeli ko le tan 

   T'awon mimo at’angeli y’o ko.


6. Laiye yi, pelu ‘gbagbo at’adua 

   L'a o ma safer ‘le Baba ohun

   Si Salem l'awon ti a si nipo 

   Npada lo; lat’ ilu Babiloni.


7. Nje awa teriba niwaju Re 

   T’Eniti ohun gbogbo jasi

  Ninu eniti Baba at’Omo 

  T’eniti Emi je Okansoso lai. Amin

English »

Update Hymn