HYMN 347

t.H.C 99 10s (FE 370)
"Emi nlo, 'lati pese aye sile fun 
nyin" Jn.14:21.  E gbo iro orin ayo orun

Orin ayo ti isegun Jesu 

Gbogbo ota l'o teri won ba 

fun Ese, iku, isa-oku pelu.


2.  O se tan lati lo gba ijoba

Fun Baba, Olorun ohun gbogbo 

O se tan lati lo gba iyin nla

T‘o ye Olori-ogun ‘gbala wa.


3.  Ohun ikanu ni lilo Re, fun 

Awon ayanfe omo-ehin Re

E mase konnu l'oro itunu 

"Emi nlo pese aye nyin sile"


4.  Orun gba lo kuro lehin eyi 

Awosanma se Olugbala mo 

Awon Ogun-orun ho fun ayo 

Fun bibo Kristi Oluwa ogo.


5.  E mase ba inu nyin je rara

Jesu, ireti wa, yio tun wa

Yio wa mu awon enia re lo 

Sibiti nwon o ba gbe titi lai.  Amin

English »

Update Hymn