HYMN 351

(FE 374) C.M.S 257 H.C 423 
t. A. &. M. 438 C.M.
"Mo si ri awon oku kekeke ati nla 
nwon duro niwaju Olorun” - Ifi. 20:121.  OKE kan mbe t’o ndan t’o ga 

Nibi t’a m’Olorun

O wa l‘okere ni orun

Ite Olorun ni.


2.  Tal’awon t’o sunmo ibe 

Lati wo ite Re?

Egbarun ‘won t’o wa nibe 

Omode bi awa.


3.  Olugbala w’ese won nu

O so won di mimo

Nwon f’oro Re, nwon f’ojo Re, 

Nwon fe, nwon si ri i.


4.  Labe opo oko tutu

La’ara won simi si

Nwon ri igbala okan won he 

Laiya Olugbala.


5.  K’awa k’o rin bi nwon ti nrin 

lpa t’o lo s' orun

Wa idariji Olorun

To ti dariji won.


6.  Jesu ngbo irele ekun

T‘o mu okan d’otun

Lori oke t’o dan, t’o ga

L’ awa o ma wo, O.  Amin

English »

Update Hymn