HYMN 357

(FE 380) C.M.S 259 H.C 247 D.S.M
“Be Ii awa o si wa Iai lodo Oluwa" 
- 1 Thess. 4:171. ‘LAI lodo Oluwa! 

   Amin, beni ko ri 

   Iye wa ninu oro na 

   Aiku ni titi lai 

   Nihin ninu ara

   Mo sako jina si 

   Sibe, alale ni mo nfi 

   Ojo kan sunmole.


2. Ile Baba loke

   Ile okan mi ni

   Emi nfi oju igbagbo 

   Wo ‘bode wura re! 

   Okan mi nfa pupo 

   S'ile na ti mo fe

   Ile didan t'awon mimo 

   Jerusalem t’orun.


3. Awosanma dide 

   Gbogbo ero mi pin

   Bi adaba Noa, mo nfo, 

   Larin iji lile

   Sugbon sanma kuro

   lji si rekoja

   Ayo ati alafia

   Si gba okan mi kan.


4. Loro ati l’ale

   Losan ati l'oru

   Mo ngbo orin orun, bori 

   Rudurudu aiye

   Oro ajinde ni

   Hiho isegun ni 

   Lekan si “Lai lod’Oluwa” 

   Amin, beni k’o ri. Amin

English »

Update Hymn