HYMN 367

(FE 389)
C.M.S 417, H.C 400 C.M
“Idile kan Ii orun ati Ii aiye" Efe 3:151. WA k’a da m’awon ore wa 

   Ti nwon ti jere na

   N’ife k'a okan ba won lo 

   S’ode orun lohun.


2. K’awon t‘aiye dorin won mo 

   T’awon to lo s’ogo

   Awa l’aiye, awon l‘orun 

   Okan ni gbogbo wa.


3. ldile kan n’nu Krist’ ni wa 
 
   Ajo kan l'a si je

   lsan omi kan lo ya wa 

   lsan omi iku.


4. Egbe ogun kan t‘Olorun 

   Ase Re l‘a si nse

   Apakan ti wo'do na ja 

   Apakan nwo lowo!


5. Emi wa fere dapo na

   Y‘o gb‘Ade bi tiwon

   A o yo s’ami Balogun wa 

   Lati gbo ipe Re.


6. Jesu, so wa, s‘amona wa

   Gba' oniko ba de 

   Oluwa pin omi meji

   Mu wa gunle I‘ayo. Amin

English »

Update Hymn