HYMN 37

C.M.S. 33 k.412 t. H.C 254 
tab 18 L.M (FE 54)
"Nibe ni awon igbekun simi po" 
- Job 3:18


1. OJO mefa t'ise koja

   Okan t'isimi si bere

   Wa, okan mi si ‘simi re, 

   Y’o s'ojo t’Olorun busi.


2. Ki 'ronu at'ope wa nde, 

   Bi ebo turari s'orun

   K’o le fa inu didun wa;

   T'o je t‘enit' O mo nikan.


3. lbale aiya orun yi, 

   L’eri isimi t'o l'ogo 

   T‘o wa fun enia mimo 

   Opin aniyan at‘aisan.


4. Olorun, a yo si ‘se Re, 

   L’oniruru t'ogbon t’otun 

   A fi 'yin ro anu t’o lo

   A ni 'reti s'eyi ti mbo.


5. F’oni sisin mimo jale

   K’o si se inu didun si;

   B'o ti dun lati l'ojo yi, 

   Nireti okan ailopin? Amin

English »

Update Hymn