HYMN 372

C.M.S 420 H.C 578 
(7.7.8.7.D) (FE 394)
"Ninu iponju Ii awa o fi de ijoba 
Orun" - Ise 14:221. OLORI Ijo t'orun 

   L'ayo l’a wole fun O 

   K'O to de, Ijo t'aiye 

   Y'o ma korin bi t'orun 

   A gbe okan wa s'oke 

   Ni ‘reti t'o ni 'bukun 

   Awa kigbe, awa f’iyin 

   F’Olorun igbala wa.


2. Gbat’ a wa ninu iponju 

   T‘a nkoja ninu ina 

   Orin ife l’awa o ko

   Ti o nmu wa sunmoO 

   Awa sope, a si yo

  Ninu ojurere Re

  lfe t'o so wa di Tire 

  Y'o se wa ni Tire lai.


3. lwo mu awon enia Re 

   Koja isan idanwo 

   “Tori O wa nitosi 

   Aiye, ese, at’esu 

   Kojuja si wa lasan

   L’ agbara Re, a o segun 

   A o si ko orin Mose.


4. Awa f'igbagbo r‘ogo 

   T’O tun nfe fi wa si 

   A kegan aiye ‘tori 

   Ere nla iwaju wa

   Bi O ba si ka wa ye

   Awa pelu Stefen t'o ku 

   Y‘o ri O bi O ti duro

   Lati pe wa lo s‘orun. Amin

English »

Update Hymn