HYMN 4

C.M.S 5, H.C 17, L.M (FE 21)
“Nigbawo ni iwo o to mi wa?" - Ps 101:2


1. WA s‘odo mi, Oluwa mi

   Ni kutukutu owuro

   Mu k'ero rere so jade, 

   Lat' inu mi soke orun.


2. Wa soda mi, Oluwa mi,

   Ni wakati osan gangan;

   Ki ‘yonu ma ba se mi ma, 

   Nwon a si s’osan mi d'oru.


3. Wa sodo mi, Oluwa mi, 

   Nigbati ale ba nle lo,

   Bi okan mi ba nsako lo, 

   Mu pada, f'oju ‘re wo mi.


4. Wa sodo mi, Oluwa mi, 

   Li oru, nigbati orun

   Ko woju mi; je k’okan mi 

   Ri simi je li aiya Re.


5. Wa sodo mi, Oluwa mi, 

   Ni gbogbo ojo aiye mi, 

   Nigbati emi mi ba pin, 

   Ki nle n'ibugbe lodo Re. Amin

English »

Update Hymn