HYMN 40

C.M.S 36, O.t.H.C. 16, L.M (FE 57)
"Awon Ii emi o si mu wa si oke mimo 
mi, emi o si mu inu won dun
ninu ile adura mi" - Isa. 56:7


1. AYO l'ojo ‘simi fun mi 

   Ati agogo at'iwasu

  Gbat a ba mi n'nu 'banuje 

   Awon l'o nmu inu mi dun.


2. Ayo si ni wakati na,

   Ti mo lo n'nu agbala Re, 

   Lati mo adun adura 

   Lati gba manna oro Re.


3. Ayo ni idahun ‘Amin‘

  To gba gbogbo ile na kan, 

  Lekokan l'o ndun t‘o nrole 

  O nkoja lo s'odo Baba.


4. B’aiye fe f'agbara de mi

   Mo ise ijo mefa re;

   Oluwa, jo tu ide na, 

   K'O so okan mi d’ominira. Amin

English »

Update Hymn