HYMN 407

C.M1. BABA anu, n’nu am Re 

   L‘ogo ailopin ntan 

   K’a ma yin oruko Re lai 

   Fun iwe mimo yi.


2. N’nu re l’awon alaini le 

   Ri oro ailopin

   Oro, t’aiye ko le fun-ni 

   T'o daju bi iye.


3. N‘nu re n’igi imo rere 

   Nfun-ni l’onje ofe 

   T'adun re po ju t’aiye lo 

   To nfa gbogbo eda.


4. N'nu re l’a gbo t’Oludande 

   Nkede alafia

   Iro didun na je iye

   At'ayo ailopin.


5. Oluwa, Oluko mimo 

   Ma sunmo mi titi

   Ko mi lati fe oro Re

   Ki nri Jesu nibe. Amin

English »

Update Hymn