HYMN 408

H.C. 268 t.H.C. 239 C.M
’Ilana re li o ti nse orin mi, ni ile 
ati po mi” - Ps.119:541. BABA orun, nin’oro Re

   Ni ogo orun ntan

   Titi lai l'a o ma yin O

   Fun Bibeli mimo.


2. Opo ‘tunu wa ninu re

   Fun okan alare

   Gbogbo okan ti ongbe ngbe 

   Nri omi iye mu.


3. Ninu re l’alafia wa 

   Ti Jesu ti fun wa

   lye ainipekun si wa

   N’nu re fun gbogbo wa.


4. lba le ma je ayo mi 

   Lati ma ka titi

   Ki nma ri ogbon titun ko 

   N’nu re lojojumo.


5. Oluwa Oluko orun 

   Mase jina si mi

   Ko mi lati fe oro re

   Ki nri Jesu nibe. Amin

English »

Update Hymn