HYMN 409

(FE 430) C.M.S 299, t.H.C 233 L.M
"Nibe l'emi o pada re, emi o si ba o 
soro lati oke ite anu wa” - Eks. 25:221. NINU gbogbo iji ti nja 

   Ninu gbogbo igbi’ponju 

   Abo kan mbe ti o daju

   O wa labe ite‐anu.


2. Ibi kan wa ti Jesu nda 

   Ororo ayo sori wa

   O dun ju ibi gbogbo lo 

   Ite anu t’a f’eje won.


3. Ibi kan wa fun idapo

   Nibi ore npade ore

   Lairi ‘ra nipa igbagbo

   Nwon y’ite anu kanna ka.


4. A! nibo ni a ba sa si 

   Nigba ‘danwo at’iponju?

   A ba se le bori esu,

  B’o se pe ko si ‘te-anu.


5. A! bi idi l’a fo sibe 

   B’enipe ajye ko si mo 

   Orun wa pade okan wa 

   Ogo si bo ite‐anu. Amin

English »

Update Hymn