HYMN 423

C.M.S 532 C.H 266 t. H.C 322 C.M 
(FE 446) 
“Ife Tire ni ki a se” - Matt. 26:42
1. lGBA aro ati ayo 

   Lowo re ni o wa 

   Itunu mi t'owo re wa 

   O si lo l’ase Re.

 
2. Bi O fe gba won l‘owo mi 

   Emi ki o binu

   Ki emi ki o to ni won

   Tire sa ni nwon nse.


3. Emi ki y'o so buburu 

   B‘aiye tile fo lo 

   Emi o w'ayo ailopin 

   Ni odo Re nikan.


4. Kil’aiye ati ekun re? 

   Adun kikoro ni 

   ‘Gbati mo fe ja itanna 

   Mo b’egun esusu.


5. Pipe ayo ko si nihin

   Oroo da l’oyin

   Latin gbogbo ayida yi

   ‘Wo ma se gbogbo mi. Amin

English »

Update Hymn