HYMN 425

C.M.S 536 H.C 386 L.M (FE 448)
"Nibiti eni meji, tabi meta ba ko ara 
won jo li oruko Mi, nibe Ii Emi o wa Ii 
arin won" - Matt. 18:201. JESU, nib'eni Re pade

   Nibe, nwon r‘ite anu Re

   Nibe, nwon wa O, nwon ri O

   lbikibi n’ile owo.


2. Ko s’ogiri t'o se O mo

   O gbe inu onirele

   Nwon mu O wa ‘bi nwon ba wa

   Gba nwon nlo le won mu O lo.


3. Olus‘agutan eni Re

   So anu Re ‘gbani d'otun

   So adun oruko nla Re

   Fun okan ti nwa oju Re.


4. Je k’a r‘ipa adua nihin

   Lati so ‘gbagbo di lile

   Lati gbe ife wa soke

   Lati gb’orun ka ‘waju wa.


5. Oluwa,‘Wo wa nitosi

   N'apa Re de ‘ti Re sile

   Si orun sokale kankan 

   Se gbogbo okan ni Tire. Amin

English »

Update Hymn