HYMN 426
C.M.S 302 H.C 278 7s. 6s (FE 449)
"Enyin ti gba emi isodomo nipa eyiti awa
fi nke pe, Abba Baba” - Rom. 8:15
1.  lWO lsun imole
     Ogo ti ko l'okunkun 
     Aiyeraiye, titi lai 
     Baba Mimo, gbo tiwa.
2.  Kanga iye ti nsan lai 
     lye ti ko l’abawon
     lye to ni irora 
     Baba Mimo, gbo tiwa.
3.  Olubukun Olufe 
     Omo Re mbe O loke
     Emi Re nrado bo wa 
     Baba Mimo. gbo tiwa.
4.  Y'ite safire Re ka 
     L'osumare ogo ntan
     O kun fun alafia 
     Baba Mimo, gbo tiwa.
5.  Niwaju ‘te anu Re 
     L'awon Angeli npade 
     Sugbon wo wa lese Re 
     Baba Mimo, gbo tiwa.
6.  Iwo a okan Re nyo 
     S'amusua t'o pada, 
     T'o mo ‘rin re lokere 
     Baba Mimo, gbo tiwa.
7.  Okan ti nwa isimi
     Okan t’eru ese npa 
     B'om’ owo ti nke f 'omu
     Baba Mimo, gbo tiwa.
8.  Gbogbo wa ni alaini 
     L’ebi, l’ongbe at‘are 
     Ko si ede f'aini wa 
     Baba Mimo, gbo tiwa.
9.  Isura opolopo
     Ko lo kojo bi Oba? 
     Ainiye, aidiyele? 
     Baba Mimo, gbo tiwa.
10.  ‘Wo ko da omo Re si 
       Omo Re kansoso na,
       Tit'O fi par‘ise Re,
       Baba Mimo, gbo tiwa.  Amin
English »Update Hymn