HYMN 43

8.7.8.7 D1. GBOGBO‘ogun orun nro keke 

   Angeli mu harpu won

   Awon mimo nt‘ohun won se 

   Lati josin t‘o l’ogo

   Ojo ‘simi t'OIorun de 

   Ojo t'o l'ogo julo

   Orun kun fun iho ayo 

   A! b’isin won ti dun to.


2. Jek'a pelu awon t‘orun 

   Yin Olorun Oba wa 

   Jek’a pa 'le okan wa mo 

   K'a f‘ohun mimo korin 

   Apere ni ti wa le je 

   T'isimi ti won loke

   Titi ao fi ri Oluwa 

   Ti a nsin l'ojukoju.


3. K’o to d’igba na, e jeki

   A ma sin l’ojo keje

   K’a f‘aniyan wa s'apakan 

   K'a pe sinu ile Re 

   O ti pase k'a ma se be

   Y'o bukun ipejo wa 

   E jek‘a sin li aisaare 

   Ere re y'o je ti wa. Amin

English »

Update Hymn