HYMN 443

K. 333 t.H.C 391. 8s 7s (FE 467) 
"Oluwa Ii Oluso-Agutan mi" - Ps. 23:11. JESU l’Olusagutan mi 

   Nje k’iberu lo jina 

   Lowo kiniun at’ekun 

   Lowo eranko ibi

   Yio so agutan Tire 

   Jesu y’o pa Tire mo.


2. Nigb‘ota fe lati mu mi 

   On ni: Agutan mi mi 

   O si ku, lati gba wa la 

   Jesu ife kil‘eyi? 

   lsegun ni ona Tire

   Ko s'ohun t‘o le se e.


3. Lona iye I'o ndari mi 

   Let' isan to nsan pele 

   Ninu oko tutu yoyo 

   Nib'ewe oro ki hu

   Nibe ni mo gbohun Jesu 

   Nibe l’o m'okan mi yo.


4. Gba mo ba nlo s’isa oku 

   B’eru tile wa l’ona

   Emi ki o berukeru 

   Tor’Olusagutan wa

   Gba mo r‘ogo at‘opa Re

   Mo mo p’agutan Re yo. Amin

English »

Update Hymn