HYMN 444

H.C 2nd Ed. 279
t.H.C 579 10s. 11s (FE 468)
“Bi enyin ko tile ri nisiyi, sugbon enyin 
ngba a gbo" - I Peteru 1:81. AIGBAGBO, bila temi l'Oluwa

   On o si dide fun igbala mi

   Ki nsa ma gbadura, On o se ranwo 

   Gba Krist’wa lodo mi ifoiya ko si.


2. B’ona mi ba su, On l’o sa nto mi 

   Ki nsa gboran sa, On o si pese, 

   Bi iranlowo eda gbogbo saki 

   Oro t‘enu Re so y'o bori dandan.


3. lfe t’o nfi han ko je ki nro pe 

   Y‘o fi mi sile ninu wahala

   Iranwo ti mo si nri lojojumo 

   O nki mi laiya pe, emi o la ja.


4. Emi o se kun tori iponju

   Tabi irora? O ti so tele

   Mo m’oro Re p’awon ajogun ‘gbala 

   Nwon ko le s’aikoja larin wahala.


5. Eda ko le so kikoro ago

   T’Olugbala mu, k’elese le ye

   Aiye Re tile buru ju temi lo 

   Jesu ha le jiya, k’emi si ma sa!


6. Nje b’ohun gbogbo ti nsise ire 

   Adun n’ikoro, onje li ogun

  B’oni tile koro, sa ko ni pe mo 

  ‘Gbana orin ‘segun yio ti dun to! Amin

English »

Update Hymn