HYMN 452

H.C 451 8s 7s (FE 477) 
"Oluwa li Oluso-agutan mi, 
emi ki o se alaini" - PS. 23:11. JESU l‘Olusagutan mi, 

   Ore eniti ki ye

   Ko s’ewu bi mo je Tire 

   T’O si je temi titi.


2. Nib’odo omi iye nsan 

   Nibe I’onm‘okan mi lo 

   Nibiti oko tutu nhu 

   L'o nf’onje orun bo mi.


3. Mo ti fi were sako lo 

   N’ife O si wa mi ri 

   L'ejika Re l'o gbe mi si 

   O f‘ayo mu mu wa le.


4. Nko beru ojiji iku 

   B’Iwo ba wa lodo mi 

   Ogo Re ati Opa Re 

   Awon l’o ntu mi ninu.


5. Iwo te tabili fun mi 

   Wo d’ororo sori mi

   A! ayo na ha ti po to! 

   Ti nt‘odo Re wa ba mi.


6. Be lojo aiye mi gbogbo 

   Ore Re ki o ye lai 

   Olusagutan, ngo yin O 

   Ninu ile Re titi. Amin

English »

Update Hymn