HYMN 462

C.M.S 180 t.H.C 161 tabi 
42 L.M (FE 487)
“Ma rin niwaju mi ki o si pe” - Gen 17:11. MO f'igbagbo b’Olorun Rin 

   Orun ni opin ajo mi

   “Op ‘at'ogo Re tu mi n'nu 

   Ona didun l'ona t'ola.


2. Mo nrin larin aginju nla 

   Nibi opolopo ti nu

   Sugbon On t‘o s‘amona wa, 

   Ko je ki nsina ti mba nu.


3. Mo nla ‘kekun t'on ewu ja 

   Aiye at’Esu kolu mi 

   Agbara Re ni mo fi la 

   Igbagbo si ni ‘segun mi.


4. Mo nkanu awon ti nhale 

   F'afe aiye ti nkoja yi 

   Oluwa, je ki nba O rin 

   Olugbala at’Ore mi. Amin

English »

Update Hymn