HYMN 47

SS 364 (FE 64)
"Olorun sanu fun mi, emi elese" - Luku 18:13


1. ELESE kan mbe to nf'anu, 

   Ati ‘dariji loni, 

   Fi ayo gba ihin t'a mu wa 

   Jesu nkoja lo nihin; 

   Mbo wa pin ‘fe ati anu 

   ‘Dariji on alafia

   Mbo wa yo l’okan elese 

   Irora ati osi.

Egbe: Jesu nkoja lo nihin, 

      Loni...loni

      Gbagbo gbat'o wa nitosi 

      S'okan re paya lati gba.

      'Tori Jesu nkoja nihin 

      O nkoja nihin Ioni.


2. Arakunrin, Jesu nduro 

   Lati dariji l‘ofe

   Ese t'o ko gba nisisiyi 

   Gbekele or'ofe Re 

   Anu ati 'fe Re sowon, 

   Ko jina si o loni

   A! silekun okan Re fun

   B'O ti sunmo tosi re. 

Egbe: Jesu nkoja lo nihin...


3. A! o mbo lati bukun o, 

  Gbo, fi irele teriba 

  Mbo wa ra o ninu ese 

  O setan lati gba o,

  lwo ha je ko ‘gbala yi 

  Ti Jesu nfi ro o,

  A! silekun okan re fun,

  B’O ti nsunmo ‘tosi re. 

Egbe: Jesu nkoja lo nihin... Amin

English »

Update Hymn